17 DAYS OF SPIRITUAL WISDOM

Yorùbá

ÀFOJÚSÙN

Ìjọ Aetherius jẹ́ gbajúgbajà ẹgbẹ́ ẹ̀mí káàkiri àgbáyé tó ń lépa ìgbàlà àti ìfòye yé ọmọnìyàn.

Ìjọ yìí ni wón dá sílẹ̀ lọ́dún 1955 láti ọwọ́ Olóògbé Ọ̀gá ti ìmọ̀ nípa ìdàpọ̀ ọmọnìyàn pẹ̀lú Ọlọ́run (Yoga), Dókítà George King. Ìkọ́ni tí ẹgbẹ́ yìí fi lọ́lẹ̀ jẹ́ èyí ti Dókítà King ń rí gba láti ìpasẹ̀ ìmọ̀ ìdàpọ̀ ọmọnìyàn pẹ̀lú Ọlọ́run (Yogic mediumship), èyí tó kún fún àwọn òye ìjìnlẹ̀ láti inú ayé àti àwọn  ààyè tó tayọ ayé yìí.

Ìmọ̀ yìí kò sí fún àyípadà Ẹ̀kọ́ tó ti wà tẹ́lẹ̀ tí àwọn kan bi Sri Krishna, Olúwa Buddha àti Ọ̀gá Jésù pẹ̀lú èyí tí àwọn yòókù gbé kalẹ̀. Ṣùgbọ́n láti mú kí ìmọ̀ gbòòrò síwájú síi kí ó sì gbòòrò karí ayé. Ọ̀kan nínú àwọn òpó ìgbàgbọ́, ìjọ yìí ni, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òjíṣẹ́ atọ́nisọ́nà tó ti wa sáyé sẹ́yìn wá láti àwọn ayé mìíràn.

Èrò tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìkọ́ni ìjọ yìí ni pàtàkì àìnífẹ̀ẹ́ ara-ẹni-nìkan àti ṣíṣe ìrànwọ́ fún ẹlòmíràn. Ìdí nìyí tí àkọmọ̀nà ìjọ yìí fi jẹ́:

“ISÌN JẸ́ WÚRÀ LÓRÍ ÀPATA AEYRÍ”

Ìjọ yìí kò rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣo nínú ọ̀nà ìfoyeyìni àti ọna kan ṣoṣo sí ìgbàlà àráyé. Ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀nà ti àwọn ẹlẹ́sìnjẹsìn ń gbà láti sọ èròngbà wọn fáwọn olùtẹ̀lé wọn nípa orísun tí ó péye. Ìtumọ̀ àmì ìjọ yìí ni “Ẹlẹ́dàá fira rẹ̀ hàn láti ipasẹ̀ ọgbọ́n”. Abala apá òsì fi àwòrán Ẹlẹ́dàá hàn gẹ́gẹ́ bí Ọba mímọ́ àti Arúgbó-ọjọ́. Àwòrán onígun mẹ́ta tó wà lápá ztún dúró fún àmì ọgbọ́n.

Koko Ìgbàgbọ́

Ẹgbẹ́ yìí nigbàgbọ́ nínú àmúgbòrò òyè, ẹ̀sìn, ìwádìí, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yálà àfojurí tàbí aláìfojúrí, lára àwọn kókó ìgbàgbọ́ náà nìwọ̀nyí:

Ìsẹ́ (Aláfinúfẹ́dọ̀ṣe) Sọ́m Làkejì

Ìsìn sọ́mọ làkejì ni a tún mọ̀sí “Karma yoga” èyí jẹ́ iṣẹ́ ẹ̀mí tó lágbára ju ti a lè ṣe, èyí ṣe pàtàkì nínú ìkọ́ni àti ẹgbẹ́ Aetherius.

Ìdápọ̀ mnìyàn Pẹ̀lọ́run (Yoga)

Eléyìí se kókó fún wíwà ní àlàáfíà àti ìlera, tàbí ìkọ́ni ní ìlànà ìgbádùn, ìdápọ̀ ọmọnìyàn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ògbólògbó ìlànà ẹ̀mí tó ń fòye yéni láì fi ìmọtara ẹni nìkan ṣe.

Agbára Ẹ̀mí, Àdúrà àti Ìwòsàn

Agbára ẹ̀mí yìí kò yàtọ̀ sí iná mọ̀nàmọ́ná tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi òfin ìsẹ̀dá tó ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìwòsàn, ìtànijí, ìtọ́sọ́nà, ìbùkún àti ìdábòbò ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́.

A lè kọ́ nípa lílo agbára ìmọ́lẹ̀, agbára ìfẹ́ láti ran ara wa lọ́wọ́, pàtàkì jùlọ níbikíbi káàkiri àgbáyé.

Agbara àdúrà máa ń ṣokùnfà agbára ẹ̀mí èyí tó máa ń darí sí àfojúsùn ẹ̀dá, tí èyí sì máa ń mú àyípadà rere wá. Mantra-tíiṣe àkàtúnkà àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ tún jẹ́ ọ̀nà ìgbàdúrà àti lílo àṣírí agbára Ọlọ́run láti ṣẹ́ ogun oríṣiríṣi. Ìwòsàn ẹ̀mí mímọ́ yìí ń ṣiṣẹ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà ẹnikẹni ló si lè mọ̀ nípa rẹ̀.

Agbára Àmì lọ́run Nínú Ẹ̀

Ìpilẹ̀sẹ̀ ìṣẹ̀dá ọmọnìyàn àti àwọn ohun gbogbo tí a dá jẹ́ ọ̀rọ̀ èṣẹ́ná làti ọdọ Ẹlẹ́dàá. Gbogbo wa, wá láti orísun tó ṣe pàtàkì. Léyìí tí a óò sì tún padà sí orísun yìí tí à ń pè ní oríṣiríṣi orúkọ bíi Ẹlẹ́dàá, Brahma, Jehovah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ẹlẹ́sìn kọ̀ọ̀kan ni ó fún ni orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìbámù pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wọn. Ayéraye ni í ṣe, Alágbárajùlọ ni, Onímọ̀jùlọ ni pẹ̀lú. Ibi gbogbo ló wà – ohun nIpilẹ̀sẹ̀-ohun-gbogbo. Kódà bíbẹ rẹ̀ kọjá òye ẹ̀dá.

Òtítọ́ ni pé tí a bá ń ṣe àpèjúwe àwọn ìrìn àjò wa nípa ìrírí, a óò rí pé òye wa ń pọ̀si nípa bíbẹ Ẹlẹ́dàá. Nípasẹ̀ báyìí a o ní alékún ìlanilóye, pẹ̀lú àlékun lórí àlékún nínú agbára ẹ̀mí, eléyìí tí a lè lò láti ṣiṣẹ́ sin ọmọnìyàn.

gbọ́n Inú Àti Agbára Ẹ̀mí Mímọ́

Ó ṣeéṣe fún gbogbo wa láti ṣe ìmúdàgbàsókè àgbọ́yé àti agbára ìrìrí tí a bínibí nípasẹ ìsìn àti ìlànà ìmúnidàgbàsókè ìdápọ̀ ọmọnìyàn pẹ̀lú Ọlọ́run (Yogic).

Àwn kọ̀ Ojú Ọ̀run Àìfojúrí (UFOs)

Gbogbo àwọn ohun tí a kà sí àwọn “ohun àìrí tó ń fo” jẹ́ àwọn ìṣẹ́-ọna fún ìṣẹ̀mí ẹ̀yìn-ìwà. Àtọdúnmọ́dún ni wọ́n tí máa ń ṣàbẹ̀wò ayé. Oríṣiríṣi àpèjúwe ni Bíbélì ṣe nípa wọn, tó fi mọ ìkùrùku ojú ọ̀run, ìràwọ̀, àti èjíjá ìràwọ̀. Kódà nínú ìwé mímọ́ ẹ̀sìn Hindu, orúkọ tí à ń pe àwọn ohun wọ̀nyí ní Vimana.

Ìgbésí-ayé Lẹ́yìn Ikú/Ẹ̀yìn-ìwà

Ìgbésí ayé míràn tó lágbára tún wà lábẹ́ ọ̀run lẹ́yìn ayé yìí. Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tíì ṣe àwárí eléyìí, torí pé ó wà lábẹ́ àkóso tó ga jùlọ sí ayé.

Nínú ìjọ Aetherius, àwọn àkóso wọ̀nyí wà ni abẹ́ ìṣàkóso àwọn tí wọ́n ń pè ni “Alákòóso àgbáyé” tàbí “Àwọn Ọlọ́run” orúkọ wọ̀nyí wà ní ẹ̀jẹ̀wọ́n bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n bá ṣe lágbára ẹ̀mí tàbí idágbàsókè ìmọ̀ nípa àwọn ohun àìrí tó.

Pẹ̀lú ìkáàánú àti ìfiraẹnijì tó lágbára, wọ́n máa ń ṣèrànlọ́wọ́ fún ọmọnìyàn láyé láìmọye ọ̀nà. Kódà bí kò bá sí ìrànlọ́wọ́ tí wọn ń ṣe wọ̀nyí, ọmọnìyàn kò bá ti ṣègbé.

Ọ̀pọ̀ àwọn Adarí Ayé tó ti wáyé sẹ́yìn ló jẹ́ pé ayé tí a wà yìí náà láti bí wọn láti jẹ́ olùkọ́ni àti olùgbàlà aráyé. Àpẹẹrẹ wọn ni Ọ̀gá Jéésù, Oluwa Buddha, Sri Patanjali, Sri Krishna, Confucus àti Lao Zi.

Ìjọ Aetherius ń fọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Alágbára Ayé nínú ìgbésẹ̀ wọn márùn-ún tí a mọ̀ ọ̀kan nínú rẹ̀ sí “ìlànà agbára àdúrà”.

Ìṣẹ̀mí nínú ìmọ̀ àti òye tẹ̀síwájú ju ayé tí ń bẹ lábẹ́ ìtànṣán òòrùn yìí lọ. Àwọn ayé míràn tún wà tí o jú èyí tí àwa yìí lọ, bẹ́ẹ̀ àwọn kan kò tó ayé yìí, bí a ṣe rí àwọn ọgbọ́n tó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ìṣẹ̀mí ọmọnìyàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí, àìrí tó ń ṣẹ̀mí lẹ́yìn ìwà ni a rí àwọn ọgbọ́n tó jẹ́ ìpalara fún ìṣẹ̀mí ọmọnìyàn láti ọdọ àwọn ẹ̀mí àìrí yìí bákan náà.

Agbara Ògóró-èyìn (Kundalini), Àwn ojú-ara àìfojúrí (Chakras) àti àdámọ́ni (Auras)

Gbogbo wa la ní àdámọ́, yálà irúfẹ́ àdámọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àfojúrí tàbí afòyemọ̀. Àwọn àdámọ́ wọ̀nyí tayọ ẹ̀yà ara tí a le fojú nìkan rí. Ṣùgbọ́n àìhànde wọn yìí kò sọpé wọn kò nípa tó jọjú lórí ìṣẹ̀mí ọmọnìyàn. Bí wọn kò bá hàndé ni àfojúrí, wọ́n hànde ní ọ̀nà mìíràn (ọ̀nà ẹ̀mí). Àwọn agbára yìí ló ń wọnú wa tó sí ń jáde látipasẹ̀ Chakras tí a tún mọ̀ sí “ìbùdó agbára ẹ̀mí mímọ́”. Bí a ṣe le fi egungun ẹ̀yìn wé egbo tí gbogbo egungun ara so mọ́ ní a le fi àdámọ́ wé òdòdó tó ń jáde níwájú ọmọnìyàn èyí tó ṣe déédé ìwọ̀n ẹsẹ kan.

Kundalini jẹ́ agbára tó kọjá àfẹnusọ èyí tí ìpìlẹ rẹ wá láti inú egungun ẹ̀yìn, èyí tí a tún lé pè ní “agbára ejò”. Ìdìdelẹ̀ agbára yìí láti ògóró ẹ̀yìn máa ń ta àdámọ́ ọmọnìyàn jí kánkán, èyí a sì máa bí ìrónú nípa àkóso-ayé. Láti fi ipá mú agbára kundalini dìde jẹ́ èyí tó léwu púpọ̀ tí ẹgbẹ́ Aetherius kò sì fọwọ́ sí rárá. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣiṣẹ́ ṣẹ sin ọmọnìyàn máa ń mú Kundalini dìde fúnra rẹ̀ láìsí wàhálà tàbí pákáleke kankan.

Àwn Akọ́ni Alágbèéga (Ascended Master)

Àwọn ènìyàn láyé ń di àtúnbí láti ni ìmọ̀ Karmic tí wọ́n sì n dẹni afẹ̀míyàn. Nígbà tí a bá ní mímọ̀ kíkún nípa ìgbésẹ̀ dídi àtúnbí, ó kù kí kálukú ó yan irúfẹ́ agbára ẹ̀mí tó fẹ́, bóyá bíbẹ̀rẹ̀ ìlànà ìkọ́ni títún nínú ayé mìíràn tó ju ayé yìí lọ ni tàbí ki ó wà láyé yìí kí ó sì di Akọ́ni Alágbèéga, kí ó sì lo ìmọ̀ yìí láti máa fi ran àwùjọ ọmọnìyàn lọ́wọ́. Àwọn Akọ́ni Alágbèéka jẹ́ alààyè tó ní òye kíkún àti agbára ẹ̀mí tó gbòòrò, pàtàkì jùlọ wọn jẹ́ ọlọ́pọ̀ àánú àti ọlọ́gbọ́n. Wọn kìí gbó gẹ́gẹ́ bí àwa ọmọnìyàn, wọn a máa pàwọ̀dà làti ipò ogbó sí ipò ọ̀dọ́ títí tí wọn yóò fi jíṣẹ ìyìnrere wọn tán.

Ìyá Ayé (Mother Earth)

Ìyá ayé jẹ́ òrìṣà tí ó fi ohun gbogbo tó ní sílẹ̀ láti pèsè ìdẹ̀ra fọmọnìyàn, ìrànlọ́wọ́ kúrò nínú ogun ìpadà sẹ́yìn àti ìwà àìlóye. Ẹgbẹ́ Aetherius ń ṣiṣẹ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un láti mú kí èròǹgbà rẹ̀ kó di ìmúṣẹ nípa ìfaraẹnijìn.

Àwn Orí Òkè Mímọ́ (Holy Mountain)

Ìjọ Aetherius máa ń ṣe àgbékalẹ̀ ìrìn àjò mímọ́ ọlọ́dọọdún sí àwọn orí òkè mímọ́ wọ̀nyí, níbi tí a tí máa ń fi agbára ẹ̀mí fún àwọn tí ó bá fẹ́, látipasẹ̀ àdúrà gbígbà, èdè-ẹ̀mí àti ìran. Àwọn orí òkè wọ̀nyí jẹ́ èyí tí àwọn Olùkọ́ni Alágbèéga ń fi ìmọ̀ ìdarí-ayé àti àkóso-ayé gbé ró nínú iṣẹ́ ìyìnree tí a pé àkọ́lé rẹ̀ ní ‘Ìtànsán/Ìmọ́lẹ̀ Ìràwọ̀ (Operation Starlight)”, èyí ló mú Dókítà King rìn ìrìn àjò àgbáyé èyí tó gbà á ní ọdún mẹ́ta gbáko.

Fún àlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́ ẹ kàn sí wá lórí ẹ̀rọ̀ ayélukára yìí:

[email protected]